'Báyìí ni orí ṣe kómiyọ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé tó jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé ní Kaduna'

Oríṣun àwòrán, Others
Olukọ kan ni ile ẹkọ Government Schools ni Kuriga nipinlẹ Kaduna, apa ariwa Naijiria ni awọn agbebọn naa ya wọ ile ẹkọ lọjọbọ ọsẹ yii, ọjọ keje, oṣu kẹta ọdun 2024, ti wọn ji awọn akẹkọọ ọgọrinlenigba ati awọn olukọ.
Sani Abdullahi lo sọ eyi nigba ti Gomina ipinlẹ Kaduna, Uba Sani ṣe abẹwo si agbegbe.
Awọn agbebọn lo yawọ ile ẹkọ LEA pẹlu ọkada lasiko ti awọn akẹkọọ naa wa ni bi ti wọn ṣe ipade owurọ ni dede aago mẹjọ abọ, ti wọn si ji awọn akẹkọọ ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọdun mẹjọ si ọdun mẹdogun.
Wọn yinbọn lu akẹkọọbinrin kan, to si wa ni ile iwosan bayii nibi to ti n gba itọju.
Gomina Sani ni awọn ẹsọ alabo ti n wa awọn akẹkọọ naa bayii.
O ni oun ti fi ọrọ naa to Aarẹ Bola Tinubu ati oludamọran fun aarẹ lori eto abo leti lori ohun to sẹlẹ ni Kunga.
“Mo ti gba ipe idaniloju lati wọ gbogbo wọn pe eto wa nilẹ lati gba awọn akẹkọọ lọwọ awọn ajinigbe.”
Sani fikun pe awọn ti gbe igbimọ kanlẹ ni Kuriga, to kun fun awọn eeyan ti ọrọ kan ni Kuriga, ẹsọ alabo ati ijọba.
Ijinigbe yii lo jẹ ohun to dẹru ba ọpọ awọn Naijiria ati awọn obi ni agbegbe Kuriga.
Ibẹruboju ni awọn olugbe agbegbe naa wa nitori gbogbo wọn lo ni ọmọ lara awọn ọmọ ti ajinigbe naa gbe lọ.
Nibayii gbogbo araalu lo woju Ọlọrun ati ijọba pẹlu ireti pe awọn ọmọ naa yo pada layọ

Olukọ sọ bi isẹlẹ naa ṣe waye
Sani Abdullahi to wa ni ile ẹkọ lasiko ti isẹlẹ naa waye, to si rapala sa kuro lọwọ ajinigbe, salaye bi wọn se wọ ile ẹkọ, ti wọn ji awọn akẹkọọ ati olukọ.
“Mo wọ ile ẹkọ ni aago 7.47am. Mo wọ ọfisi adele ọga ile ẹkọ lati lọ buwọlu iwe.
“Sadede ni Adele ọga ile ẹkọ ni ki n wo ẹyin mi, nigba ti mo kọ ẹyin, mo ri pe awọn agbebọn ti ya wọle si gbogbo ayika ileẹkọ.
“Gbogbo nnkan daru, a ko mọ ibi ti a ma ya si. Nigba to ya, awọn agbebọn ni ka wọ inu igbo, a gbọ si wọn lẹnu. Ori lo ko wa yọ ati awọn yooku to tẹle wa.
“Mo pada sinu abule lati pe akiyesi araalu . Ni kiakia ni awọn ẹsọ alabo KADVS tẹlẹ awọn ajinigbe naa sugbọn wọn ko ri wọn mu rara.
“Koda awọn ajinigbe ṣekupa eeyan kan lara awọn ẹsọ alabo to tẹle wọn.
Abdullahi ni awọn araalu gbiyanju lati dola awọn ọmọ sugbọn awọn ajinigbe kọju ija si wọn, ti wọn si ṣekupa eeyan kan larin wọn.

Oríṣun àwòrán, Others
A o ri pe a gba awọn akẹkọọ pada- Gomina Uba Sani
Gomina ipinlẹ Kaduna, Uba Sani ti fi da awọn araalu Kuriga pe ijọba yoo gbe gbogbo igbesẹ lati ri pe awọn akẹkọọ naa pada ni alaafia.
O ni, “Mo ti sọ fun Aarẹ ati Oludamọran lori eto aabo lori isẹlẹ Kuriga, ti mo si gba aridaniloju pe wọn yoo gbe igbesẹ lati gba awọn akẹkọọ ati olukọ."

Oríṣun àwòrán, Kaduna Govt
Agbébọn jí akẹ́kọ̀ọ́ tó lé ní 280 gbé lọ nílè ẹ̀kọ́ girama àti alákọ̀bẹ́rẹ̀

Oríṣun àwòrán, getty images
Akẹkọọ to le ni 280 lawọn agbebọn ti ji gbe niluu Kuriga, agbegbe Chikun, to wa ni ipinlẹ Kaduna.
Isẹlẹ naa lo waye lowurọ Ọjọbọ, ọjọ keje, oṣu Kẹta, ọdun 2024, lasiko ti awọn akẹkọọ naa pejọ ni ago mẹjọ abọ owurọ fun adura, ki awọn agbebọn ọhun to yabo ile ẹkọ naa lori alupupu, ti wọn si ji wọn gbe.
A gbọ pe ọjọ ori awọn akẹkọọ ọhun ko ju ọdun mẹjọ si marundinlogun lọ.
Awọn akẹkọọ naa, pẹlu awọn olukọ wọn ni awọn agbebọn ọhun ji gbe.
Iroyin ijinigbe ni iha Ariwa Naijiria kii ṣe iroyin tuntun amọ ijinigbe ọlọgọọrọ eeyan ti din ku laarin ọdun diẹ sẹyin titi di ọsẹ to kọja.
Gomina ipinlẹ Kaduna, Uba Sani ti fidi iroyin naa mulẹ.
Sani sọ pe akẹkọọ 187 ni wọn ji gbe nile ẹkọ Government Secondary School, nigba ti wọn ji awọn 125 mii gbe nile ẹkọ alakọbẹrẹ kan, amọ marundinlọgbọn ninu wọn ti pada wale.
Ẹnikan ti iṣẹ̀lẹ̀ naa ṣoju rẹ̀ sọ fun awọn akọroyin pe, awọn agbebọn naa yinbọn lu ọkan lara awọn akẹkọọ ọhun ṣugbọn o ti n gba itọju nile iwosan.
Ọkan lara awọn olukọ ti ori ko yọ sọ pe awọn araalu gbiyanju lati doola awọn akẹkọọ naa lọwọ awọn ajinigbe, amọ agbara awọn agbebọn naa ju ti awọn araalu lọ.
Gbogbo mọlẹbi to n gbe lagbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye ni igbagbọ wa pe ọmọ wọn wa lara awọn ti wọn ji gbe lọ.
Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin ọjọ diẹ ti awọn afurasi Boko Haram ji awọn obinrin to n wa igi idana ninu igbo gbe lọ nipinlẹ Borno.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Inu ibẹru-bojo ni ọpọ awọn araalu lati igba ti wọn ti ji awọn akẹkọọ naa gbe lọ.
Ninu oṣu Kinni ni awọn agbebọn kan yawọ agbegbe Kuriga, ti wọn si ṣekupa ọga ileẹkọ, ti wọn si tun ji iyawo rẹ gbe.
Kuriga jẹ abule kan to wa loju ọna Kaduna si Birnin Gwari.
Boko Haram jí èèyàn tó lé ní ‘300’ gbé ní Borno

Oríṣun àwòrán, others
Ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta, ọdun 2024, ni ọmọ ogun alakakiti Boko Haram ji ọgọrọ eeyan gbe lọ nipinlẹ Borno.
Ilu Ngala, ti ko fi bẹẹ jina si orilẹ-ede Cameroon ni a gbọ pe iṣẹlẹ naa ti waye.
Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le sọ iye eeyan ti ọrọ naa kan, awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan ni Naijiria ni awọn eeyan ti Boko Haram ji gbe le ni ọọdunrun.
Awọn alaṣẹ sọ pe wọn ji awọn eeyan naa gbe lasiko ti wọn n lọ ge igi idana ninu igbo.
Iroyin ni pupọ ninu awọn ti wọn ji gbe ni wọn jẹ obinrin.
Ileeṣẹ iroyin AFP jabọ pe obinrin mẹtadinlaadọta ni awọn mọlẹbi wọn ṣi n wa bayii.
Iroyin ni agọ awọn ogunlende ni awọn eeya ti wọn jigbe naa n gbe.
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ijọba ipinlẹ naa ko tii sọ ni pato iye eeyan ti ọrọ naa kan.
Ọkunrin kan ti ko fẹ ki a fi orukọ oun lede ni “Lọjọ Aiku, a gbọ pe awọn ogunlende kan n ge igi idana ninu igbo ki Boko Haram to lọ ji wọn gbe.
“O le ni igba eeyan to wọ inu igbo naa lati ge igi ṣugbọn wọn ni ọgọrun eeyan ati mẹtala ninu wọn ti wọn jigbe, wọn si fi awọn arugbo atawọn ọmọ wẹwẹ inu wọn silẹ ki wọn maa lọ.
To ba jẹ pe pe lootọ ni iye awọn ti wọn ji gbe jẹ 319 gẹgẹ bi awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan ṣe n jabọ, yoo jẹ iye eeyan to pọju ti Boko Haram yoio ji gbe ninu itan Naijiria lẹyin ti wọn ji awọn akẹkọọ Chibok ti iye wọn jẹ 276 gbe lọ lọdun mẹwaa sẹyin.
Iṣẹlẹ ijinigbe yii lo n waye lẹyin ti ijọba Borno kede pe ida 95% awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram ipinlẹ naa lo ti jọwọ ohun ija wọn tabi ti awọn ologun ti pa.












